Shettima Mustapha

Shettima Mustafa
Federal Minister of Agriculture
In office
August 1990 – 1992
Federal Minister of Defense
In office
17 December 2008 – 14 July 2009
AsíwájúMahmud Yayale Ahmed
Arọ́pòGodwin Abbe
Federal Minister of Interior
In office
14 July 2009 – 17 March 2010
AsíwájúGodwin Abbe
Arọ́pòEmmanuel Iheanacho
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Kọkànlá 1939 (1939-11-26) (ọmọ ọdún 84)
Nguru, Ìpínlẹ̀ Yòbè, Nàìjíríà

Shettima Mustafa OFR (Tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1939 - 2022) jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti olóṣèlú ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Mínísítà fún ètò ọ̀gbìn laarin ọdún 1990 sí ọdún 1992. Ní ọdún 2007 wọ́n yan Shettima gẹ́gẹ́ bi Mínísítà fún àbò sínú ètò ìṣàkóso ti Umaru Yar'Adua. Lẹhinna ni Ó wá di Mínísítà fún Interior.[1] Shettima fi offici sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mínísítà ní oṣù kẹta ọdún 2010 nígbàtí adelé aàre Goodluck Jonathan tú Ìgbìmọ̀ Ìṣàkóso rẹ̀ ká.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀

Shettima Mustafa ni wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kọkanla ọdún 1939 ní Nguru, agbègbè tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Yòbè bayi. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ti Borno Middle ní Maiduguri laarin ọdún 1946 si ọdún 1952. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Medical Field Assistant ní Kánò laarin ọdún 1955 sí ọdún 1956. Ó tún ṣiṣẹ́ ní Borno Native Administration laarin ọdún 1954 sí ọdún 1964 kí ó tó di wípé Ó lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ Radio Television ti Kàdúná laarin ọdún 1965 sí ọdún 1967. Nígbàtí Shettima pé ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ní ọdún 1967, wọ́n gbà á gẹ́gẹ́ bí akọ́ ẹ̀kọ́ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ahmadu Bello . Ó kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè ní ọdún 1972 tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùwádì ìjìnlẹ̀ pẹ̀lú ilé-ẹ̀kọ́ gíga fún ìwádì ìjìnlẹ̀ lórí àwọn ǹkan ọ̀gbìn. Láti ọdún 1973 sí ọdún 1974, Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Cambridge níbití Ó ti gba ìwé ẹ̀rí onípele gíga ti Dípúlómà (Postgraduate Diploma) nínú Applied Biology. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ láti gba ìwé ẹ̀rí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ (PhD) nígbàtí Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Purdue, Indiana ní ìlú Améríkà ní ọdún 1978. Ó gba ìwé ẹ̀rí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yí ní ọdún1979. Shettima tún parí ẹ̀kọ́ kan lórí Agricultural Project monitoring and evaluation ní Yunifásítì ti East Anglia ní ọdún 1990.

Iṣẹ́ ìlú

Shettima Mustafa ní wọn yàn gẹ́gẹ́ bi kọmíṣọ́nà sínú ìjọba ní Ìpínlẹ̀ Borno lábẹ́ gómìnà Mohammed Goni. Shettima ń gòkè ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé nínú ipò òṣèlú títí ó fi di wípé wọn yan an gẹ́gẹ́ bí olùdíje fún Igbákejì aarẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Nigeria People's Party nínú ìdìbò ti ọdún 1983. Síbẹ̀síbẹ̀, aláṣẹ Shehu Shagari ti ẹgbẹ́ òṣèlú National Party of Nigeria ló borí nínú ìdìbò yí. Lẹ́hìn tí àwọn ológun fi ipá gbà ìjọba ní oṣù kejìlá ọdún 1983 nígbàtí ọ̀gágun Muhammadu Buhari gun orí àléfà, wọ́n fi Shettima sínú ẹ̀wọ̀n títí di ọdún 1985. Nígbàtí Ó jáde nínú ẹ̀wọ̀n, Ó padà lọ sẹ́nu iṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Maiduguri. Lẹhinna ni Ó di olórí agbàgbè ní ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ti o nri si ètò ọ̀gbìn (Federal Ministry of Agriculture) ní ìlú Jos. Ní oṣù kẹjọ ọdún 1990, wọ́n yan Shettima Mustafa gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún ètò ọ̀gbìn àti ohun àlùmọ́nì (Minister of Agriculture and Natural Resources). Orí ipò yí ni Ó wà títí di ìgbàtí wọ́n fi tú Ìgbìmọ̀ Mínísítà ká ní ọdún 1992.

Lẹ́hìn ìwọ̀nyí, Ó di olùdámọ̀ràn fún oríṣiríṣi àwọn àjọ ilé-iṣẹ́ ní agbègbè àti ní ìlú òkèèrè. Ó sì tún di akápò ti orílẹ̀ èdè fún ẹgbẹ́ alábùradà (People's Democratic Party). Orí ipò yí ló wà laarin ọdún 1998 sí ọdún 2001. orísirísi ẹgbẹ́ àti àwùjọ ni Shettima wa. Àwọn bi i Fellow of the Genetic Society of Nigeria, American Society of Agronomy àti ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn onímọ̀ nípa ọ̀gbìn ní ilẹ̀ Nàìjíríà (Agricultural Society of Nigeria). Ní ọdún 2002, wọ́n yan Shettima Mustafa sínú ìgbìmọ̀ olùdarí ilé ìfowópamọ́ ti Savannah, bótilẹ̀jẹ́pé ki i se ọ̀kan lára àwọn alájọpín ìdókòwò.[3]

Mínísítà Yar'Adua

Alákòso orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Umaru Yar'Adua yan Shettima gẹ́gẹ́ bi Mínísítà fún ètò àbò.[4] Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù keje ọdún 2008, Ó paro àyè pẹ̀lú [ [Godwin Abbe] ] láti di Mínísítà fún Interior.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

  1. "New Nigerian ministers nominated". Al Jazeera. 2008-11-20. Retrieved 2020-03-26. 
  2. "Jonathan sacks ministers". Vanguard News. 2010-03-17. Retrieved 2020-03-26. 
  3. "Budget '09 still hangs, Senate to screen 13 ministers". WRITER AND PROOFREADER. 2004-02-26. Retrieved 2020-03-26. 
  4. "Nigeria's President Names New Cabinet After Weeks of Speculation". IHS Markit. 2007-07-27. Retrieved 2020-03-26. 
  5. "Cabinet Shake-up : Yar’Adua moves Godwin Abbe to Defence Ministry". Vanguard News. 2009-07-14. Retrieved 2020-03-26.