Yu Xu

Àdàkọ:Family name hatnote

Yu Xu
Àwòrán Yu pẹ̀lú ọkọ̀ òfuurufú tí àwọn ọmọ ogun òfuurufú ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní Langkawi, lórílẹ̀-èdè Malaysia.
Orúkọ àbísọÀdàkọ:Zh
Ọjọ́ìbíMarch 1986
Chengdu, Sichuan province, China
Aláìsí12 November 2016 (ọmọ ọgbọ́n ọdún)
Hebei, China
Orílẹ̀-èdèChinese
Iṣẹ́Ọmọ-ogun awakọ̀ Òfurufú

Yu Xu Tí wọ́n bí lóṣù Kẹta ọdún 1986, ó sìn ṣaláìsí lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kọkànlá ọdún 2016)[1][2] jẹ́ ọmọgun-bìnrin adarí àwọn awakọ̀ òfuurufú ọmọ orílẹ̀-èdè China tí ó dárí ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n ń pè ní August 1st Aerobatic Team tí àwọn ọmọ-ogun People's Liberation Army Air Force.

Ìgbà èwe rẹ̀

Wọ́n bí Yu sí Chengdu, olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Sichuan lápá gúúsù ìwọ̀-oòrùn China.[3]

Ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀

Yu wọ ilé-ẹ̀kọ́ ọmọ-ogun PLA Air Force Aviation University lọ́dún 2005, ó sìn kàwé jáde lọ́dún 2009.[4][5] Sixteen women (including Yu) had graduated that year, which made her among the first women certified to fly fighter jets.[3]

Iṣẹ́

Yu dára pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ogun òfuurufú ti People's Liberation Army Air Force lóṣù kẹsàn-án ọdún 2005. Yu farahàn ní ibi ayẹyẹ CCTV New Year's Gala pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun obìnrin awakọ̀ òfuurufú ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́dún 2010.[3] In 2012, she was certified to fly the Chengdu J-10, single-engine jet.[1]

Ikú rẹ̀

Yu ṣaláìsí níbi ìkọ́ṣẹ́ awakọ̀ òfuurufú lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kọkànlá ọdún 2016 lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfuurufú mìíràn tí J-10 ṣèṣì ṣáná sí kọlù ú.[6] Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun ṣàlàyé pé, Yu kò tètè bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú rẹ̀ lásìkò tí wọ́n kọ lù ú ló fà ikú rẹ̀ [7] Ìròyìn mìíràn láti ọwọ́ àwọn ọmọ ogún gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn China Daily ṣe sọ ṣàlàyé pé, Yu tètè bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú rẹ̀ lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfuurufú mìíràn kọlù ú, ṣùgbọ́n apá ọkọ̀ Òfurufú mìíràn ló kọlù ú, tí ó sìn fa ikú rẹ̀. Ìròyìn náà tẹ̀ síwájú pé akẹgbẹ́ rẹ̀ ọkùnrin tí wọ́n dìjọ wà nínú ọkọ̀ òfuurufú náà jáde nínú rẹ̀ láì farapa. Àtipé, ọkọ̀ òfuurufú kejì náà padà balẹ̀ láìfarapa. Lórí Weibo, wọ́n kan sáárá sí Yu Xu gẹ́gẹ́ bí akọni ológun. Wọ́n sìn kọ ọ́ síbẹ̀ báyìí pé "Yu Xu ní ọmọ-ogunbìnri awakọ̀ Òfurufú tí a lè fi yangàn julọ. Àdánù ńlá gbáà ni ikú rẹ̀ jẹ́ fún orílẹ̀-èdè wa". Wọ́n gbé eérú òkú rẹ̀ lọ fún ayẹyẹ ìkẹyìn ní gbọ̀ngán eré-idaraya kan, tí ọ̀pọ̀ èèyàn bí i 360,000 wá káàkiri orílẹ̀ èdè China láti wá kẹ́dùn rẹ̀ pẹ̀lú òdòdó ìkẹ́dùn. Lẹ́yìn èyí, wọ́n kó eérú òkú rẹ̀ padà sí ìlú rẹ̀, Chongzhou lápá gúúsù ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Sichuan, wọ́n sìn sin òkú rẹ̀ pẹ̀lú sàréè gẹ́gẹ́ bí òkú ẹni rere.

Àwọn Ìtọ́kasí