Raila Odinga

Raila Amollo Odinga
Odinga attending the 2009 World Economic Forum on Africa, June 2009.
Prime Minister of Kenya
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
17 April 2008
ÀàrẹMwai Kibaki
AsíwájúJomo Kenyatta (1963 – 1964)
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí7 Oṣù Kínní 1945 (1945-01-07) (ọmọ ọdún 80)
Maseno, Kenya
Ẹgbẹ́ olóṣèlúODM
(Àwọn) olólùfẹ́Ida Odinga (born 1950)

Raila Amollo Odinga (born January 7, 1945) je oloselu omo ile Kenya, lowolowo o je Alakoso Agba ile Kenya ninu ijoba idarapo.

A bí i ní Maseno, Kizumu District, Nyanza Prorince ní January 1945. Ó rí ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ní 1965 èyí tí ó fi lọ kàwé ní Technical University of Magdeburg (tí ó jẹ́ ara Otto von Gueriche University of Magdeburg) ní East Germany. Ní ọdún 1970, ó jáde ó si gba oyè lórí Mechanical Engineening. Nígbà tí ó dé Kenya, ó ṣe olùkọ́ ní University of Naírobì kí ó tó lọ máa ṣe òṣèlú. Ní ọdún 1975, wọ́n sọ ọ́ di Deputy Director of the Kenya Burean of Standards iṣẹ́ tí ó ṣe títí tí wọ́n fi sọ ọ́ sí ìhámọ́ ní 1982. Wọ́n fi i sílẹ̀ ní oṣù kẹfà 1988, wọ́n tún tún un mú ní oṣù kẹ́jọ. Wọ́n fi sílẹ̀ ní ọjọ́ kejìlá oṣù kéfà 1989 wọ́n tún mú un padà ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kéje ọdún 1990 pẹ̀lú Keneth Matiba àti Charles Rubia. Bí wọ́ ṣe dá a sílẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà ọdún 1991, ńṣe ni ó sá gba Norway lọ Ó ní wọ́n fẹ́ pa òun. Ó padà sí Kenya ní 1992, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú FORD eyí tí baba rẹ, Jaramongi Oginga Odinga ń darí. Nígbà tí bàbá rẹ̀ kú ní oṣù kìíní ọdún 1994 tí Michacl Waimalwa kijana di olórí ẹgbẹ́ náà Raila ta kò ó ṣùgbọ́n ó fidí rẹmi èyí ló mu un (Raila) kúrò nínú ẹgbẹ́ náà tí ó sì lo dara pọ̀ mọ́ National Development Party (NDP).


Itokasi