Fránsíọ̀m tabi Francium, mimo tele bi eka-caesium ati actinium K,[akiyesi 1] je apilese kemika to ni ami-idamo Fr ati nomba atomu 87. O ni ikan ninu awon odionina tokerejulo larin gbogbo awon apilese ti a mo, bakanna ohun ni apilese aladanida keji tosowonjulo (leyin astatine). Fransiom je onide to je radioalagbara giga to n jera si astatine, radium, ati radon. Gege bi onide alkali, o ni agbara elektroni kan.
Francium je wiwari latowo Marguerite Perey ni Fransi (nibi ti apilese yi ti ri oruko) ni 1939. Ohun ni apilese togbeyin ti o je wiwari ninu adanida, kanran jije sisopapo.[akiyesi 2] Lode yara ise-idanwo, francium sowon gidigidi, iye ipase je wiwari ninu alumoni aladalu uranium ati thorium, nibi ti isotopu francium-223 ti n je didasile to si n je jijera bibaun. Iye to kere bi 20–30 g (ounce kan) lowa nigba yiowu kakiri inu igbele Aye; awon isotopu yioku je alasopapo yanyan. Iye titobijulo ti o je kikojo lai isotopu yiowu ni isupo bi awon atomu 10,000 (ti francium-210) ti won je didasaye gege bi efuufu tutugidi ni Stony Brook ni 1997.[1]